ISOKAN OMO ODUDUWA
Alafia ti o lopin ko je ipin gbogbo omo Odudua patapata.
Mo royin, mosi beyin, eje ka je ikan. Ote man teniri ni o. Kosi ohun kan bayi to da ninu ote, ko si si ohun kan daradara to le tinu ote jade wa.
Eje ka se ara wa lokan, eje kase rawa losusu owo. Ile taba fi'to mo, irin nio wo. Eja ka fi ote ati ohun gbogbo to ya wa sile. Gbogbo ohun ton da isokan wa lamu, eje ka fi sile patapata. Agbajowo lafi n soya, ajaji owo kan o gberu do ri. Ninu isokan ni itesiwaju ati idagbasoke to ye. E mase je ki ipo oselu tabi ipokipo, owo, wiwa agbara tabi ohun kohun muwa ko eyin si ara wa. Ikan ni wa ninu odudua, eje ka parapo gbe orile Yoruba ga.
Ema se jeki a gbagbe ede, asa ati ise wa. Awon eko to ni itumo ninu asa ati ise wa, ka ma se je ka sonu pelu asa igbalode. Eje ka gbe won laruge.
Ohun kohun ti enikeji bati se to lodi, eje ka fori ji. Taaba gbagbe oro eyin, aho ni reni basere. Ikan niwa o. Eje ka gba idariji laye. Ninu eyi aho tesiwaju.
Eje ki a ran enikeji to ba se nkan tabi wa nkan rere lowo, kiise ka wa ona ati jalule. Eni to ba fe goke, ko mase wa isubu enikeji. Eje ka ti arawa leyin si ipo iserere bi igba eke ti nfowo tile, ti igba alamu ti nfowo ti ogiri.
Enikeni to ba wa ni ipo giga, koma se fi oju pa awon eniyan tie re. Eje ka lo ipo wa lati fa ara wa soke. Ohun to dara niyen.
Ninu isokan a ma roke ni, ninu isokana ama bori, ninu isoka a ma tesiwaju. Eyin ati emi.
Ki Edumare saanu gbogbo wa.
Comments
Post a Comment